OJÚ ÀMÚWAYÉ YORÙBÁ ÀTI ÌBÁYÉMU NÍNÚ EWÌ‘Ẹ FARA BALẸ’ TÍ AKÍNWÙNMÍ ÌṢỌ` LÁ KỌ
Keywords:
Ojú àmúwayé, Àwùjo. Yorùbá, Ojú àmúwayé Yorùbá, Tíq´rì Ìmq`-ìfojú-inú-wò, Ewì Akínwùmí Ìs. o. `láAbstract
Alárògún aláròjinlẹ` ni àwọn Yorùbá. Wọ´n ní àrògún dé ibi pé, èrò ìjìnlẹ` wọn máa ń sáábà ní ṣe pẹ`lú ìgbé ayé ọmọ ẹ`dá. Yorùbá a má wo sààkun ayé, ìgbà àti àkókò,ìrìnkèrindò ọmọnìyàn láwùjọ, ìṣesí ẹni, àyànmọ´ ènìyàn, ìgbésẹ` ẹ`dá láyé, àfọwọ´fà ẹ`dá, àìgbọràn, àìfarabalẹ`, àìlẹ´ẹ`kọ´ ilé, aìbọ`wọ` fágbà, àìmọyì ara ẹni, ìgbéraga, ìruga ọkàn, àìnáání ẹbí, ọ`rẹ´ àti ojúlùmọ`, ìṣelòdì sí òfin ìlú, àìníbẹ`rù Ọlọ´rún àti àwọn Òrìṣà tí ó jẹ´ agbẹnusọ ọmọ ènìyàn níwájú Olódùmarè. Èrò Yorùbá nípa ìrírí wọn ìgbàanì ni ó mú kí wọn ní àròjinlẹ` lórí ọ`nà tí wọn ó gbàṣe ìgbé ayé wọn. Ojú àmúwayé Yorùbá lórí àìfẹ`lẹ´ kébòòsí ẹ`dá nínú ìdojúkọ wọn láyé, lórí ìwa wàdùwàdù, ìwa mo gbọ´ntán, mo mọ` tán ló mú Ìṣọ`lá kọ ewì ‘Ẹ fara balẹ`’ nígbà tí ó ṣe àkíyèsí èrò àwọn Yorùbá lórí bí ayé ṣe dà. Ọgọ`ọ`rọ` àwọn edèyàn ni wọn ò kọ´gbọ´n lára ìṣẹ`lẹ` tí ó ti ṣẹlẹ` sí àwọn kan rí, yálà ìṣẹ`lẹ` ire tàbí ibi, èyí ló sì mú Ìṣọ`lá kọ irú ewì báyìí. Ìtúpalẹ` ewì ‘Ẹfara balẹ`’ ni pépà yìí dá lé lórí láti lè ṣe àgbéyẹ`wò èrò àwọn Yorùbá lórí ìrú ìmọ`ràn tí Ìṣọ`lá ń gba àwọn ènìyàn láwùjọ.Tíọ´rì Ìmọ`-ìfojú-inú -wò ni a ṣe àmúlò gẹ´gẹ´ bí i tíọ´rì tí ó wà ní ìṣewẹ´kú pẹ`lú ìtúpalẹ` ewì ‘Ẹ fara balẹ`’nítorí tíọ´ rì yìí ní ṣe pẹ`lú àgbékalẹ` èrò ọkàn òǹkọ`wé nínú iṣẹ´ rẹ`. Bákan náà ni a ṣe àyẹ`wò iṣẹ´ àwọn ẹni ìṣáájú lórí ìtumọ` ohun tí ojú àmúwayé jẹ´ lágbàáyé àti láwùjọ àwọn Yorùbá,bẹ´ẹ` ni a sì wo onírúúrú àwọn ẹ`yà ojú àmúwayé àti ojúṣe rẹ` nínú ìgbé ayé ẹ`dá.Pépà yìí ṣe ìtúpalẹ` kókó- ọ`rọ` inú ewì ‘Ẹ fara balẹ`’ ó sì ṣe àfihàn iṣẹ´ tí Ìṣọ`lá fi ewì naà jẹ´ fún àwùjọ ní ìlànà ojú àmúwayé àwọn Yorùbá àti bí ewì náà ṣe wà ní ìbámu pẹ`lú ìṣẹ`lẹ` àwùjọ lóde òní.